EYIN AYA, E TERIBA FUN AWON OKO YIN
Eph. 5:22-6:9
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 24/02/2016
- Eyin aya, E teriba fun awon oko yin
Gege bi ijo, ti nteriba fun Jesu Oluwa
Eyi ni eto Olorun
Ki oko je ori fun iyawo re
Gege bi Baba, ti je ori fun, Kristi
Ati nitori eyi, fun aya lati ma teriba fun oko re
O je lati da ori eto Olorun, kodo.
Egbe: Emi yo gboran, si ase Olorun mi
Mo mo pe nipa gbigboran si
Ni ibukun Re yi o je temi
Botiwukori, emi yo gboran
Ohunyowu ki eniyan se si mi
Oro Olorun l’emi yo te le
Ranmilowo Baba, k’emi le gboran.
-
Eyin oko, E feran awon aya yin denu
Gege bi Jesu, ti f’emi Re lele fun ijo Re
Oko t’o feran aya re
O feran ara ohun tikarara re
Bayi ni Olu-wa wi fun awon, oko
Ati nitori eyi, ti oko ba ko lati feran aya ti re
O je lati tapa si ase Olodu-mare. -
Eyin obi, E fi ogbon to awon omo yin
Ninu ilana, eko ati iberu Olorun
E ma si se mu won binu
Sugbon ki E ko won l’oro Olorun
Ti won ba dagba, won yo je eni, rere
Ati nitori eyi, ti obi ko ba to omo re l’ona to to
O je lati mu ki omo di eni bu-buru. -
Eyin omo, E maa bowo fun awon obi yin
Eyi ni ase, Olorun pelu awon ileri
Omo t’o gbo ti obi re
Ni yo ni emi gigun ni aye yi
Ohun t’e ba gbin, ni omo yo san, fun yin
Ati nitori eyi, ti omo ko ba gboran si obi re l’enu
O je lati mura fun ijiya ti O-lorun. -
Omo-odo, E maa gboran si oga yin l’enu
Ni iwariri, ati pelu iberu Olorun
Pelu otito inu yin
Bi enipe Kristi ni E nsise fun
Jesu Oluwa, ni yo san ere, fun yin
Ati nitori eyi, ti omo odo ko ba gboran si oga re
O je l’ati padanu ere l’odo O-lorun. -
Eyin oga, E maa din awon iberu yin ku
Ki E ranti pe, eyin pelu ni oga ni orun
Ohunkohun ti E ba gbin
Si’nu aye awon omo-odo yin
Ni eyin pelu, yo ka l’odo O-lorun
Ati nitori eyi, ti oga ba nfi iya je omo-odo re
O je l’ati gba ijiya li odo O-lorun.