HYMN – BABA IWO L’O YE

BABA IWO L’O YE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 01/10/2016.

 1. Baba Iwo l’o ye /2ice. 1527
  Oro aye mi o
  Baba iwo l’o ye o
  Gbogbo won l’o ye O.

Egbe: Baba Baba (Baba mi l’orun). 1528
Iwo nikan l’O le ran mi l’owo
Eleda mi (Oba ayeraye)
Tete da si oro aye mi.

 1. Baba tete muse /2ice.
  Ileri Re fun mi
  Baba tete muse o
  L’oni yi mu won se.

 2. Baba sure fun mi /2ice.
  K’aye mi k’o roju
  Baba sure fun mi o
  K’aye mi k’o toro.

 3. Baba ranmilowo /2ice.
  L’ori idile mi
  Baba ranmilowo o
  K’ile mi k’o l’ayo.

 4. Baba pese fun mi /2ice.
  K’emi rije rimu
  Baba pese fun mi o
  Le osi mi lo o.

 5. Baba segun fun mi /2ice
  K’Esu ma bori mi
  Baba segun fun mi o
  K’O gbe mi leke o.

 6. Baba wa mi si mi /2ice.
  K’e mi ma rewesi
  Baba wa mi si mi o
  F’agbara kun mi o.

 7. Baba mu mi duro /2ice.
  K’ese mi ma se ye
  Baba mu mi duro o
  Ki ntele O d’opin.

 8. Baba mu mi de’le /2ice
  K’e mi ma ku s’ona
  Baba mu mi de’le o
  Ki nba O j’oba o.