HYMN – OBA IYE, OBA OGO, JESU KRISTI

OBA IYE, OBA OGO, JESU KRISTI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 5/1/2017.

Egbe: Oba iye, (iye) Oba ogo (ogo)
Jesu Kristi, ko s’eni bii Re rara.

  1. Tal’eni t’o nla’ju afoju? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o nji oku dide? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’oluwosan bi ti Re rara.

  2. Tal’eni t’o nwe adete mo? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o ngb’amukun dide? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’onisegun bi ti Re rara.

  3. Tal’eni t’o ro’jo lat’oke? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o nmu ‘rugbin dagba? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’alagbara bi ti Re rara.

  4. Tal’eni t’o nwe elese mo? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o nfun ni ni’gbala? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’olugbala bi ti Re rara.

  5. Tal’eni t’o nmu ni ri Baba? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o ndahun adura? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’oluranwo bi ti Re rara.

  6. Tal’eni t’o nf’aboyun l’oyun? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o ns’eyin d’akuko? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’oniyanu bi ti Re rara.

  7. Tal’eni t’o nmuni sun k’aji? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o si’lekun orun? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko tun s’alabo bi ti Re rara.

  8. Tal’eni t’o nb’aini pade? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o nba ni tan ‘soro? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’olupese bi ti Re rara.

  9. Tal’eni t’o p’Esu l’enu mo? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o fun ni ni’segun? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’olugbeja bi ti Re rara.

  10. Tal’eni t’o nfun ni n’isimi? (Iwo ni Oluwa)
    Tal’eni t’o nfun ni ni ayo? (Iwo nikan ni momo o)
    Ni gbogbo agbaye, (ati ni gbogbo orun)
    Ko s’agborodun bi ti Re rara.