ONIGBAGBO SORA O
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 16/1/2017.
Egbe: Onigbagbo sora o (sora)
Ma se ba won ko egbe aye rara
Iwa ati’se re l’aye o (la’ye o)
Ni ki o fi gb’Oluwa re ga.
-
Ma s’epe mo rara
Ma puro ore mi
Oro t’o je mo ija
K’a ma se gbo l’enu re -
Ma jale mo rara
Ma w’ose awure
Iwa ti tete tita
Ka ma se ri l’owo re -
Ma se sina rara
Ma muti ore mi
Oro asoju siso
K’a ma ba o ni’di re -
Ma k’ore buburu
Ma se rin’rinkurin
‘Biti Jesu ko nii lo
Ka ma ri o l’ona ‘be -
Ma wo’so buburu
Ma wo f’aya-sile
Aso awon pansaga
K’a ma se ri l’orun re. -
Ma ko’rin buburu
Ma wo’ran ese mo
Aworan onihoho
K’a ma se ba ni’le re. -
Ma si’se buburu
Ma ta’ja ese mo
Ohunkohun t’o lodi
K’a ma se ba ni’gba re. -
Ma r’ero buburu
Ma jowu ore mi
Ibinu igberaga
K’o ma se si l’aye re.