OBA ATOFARATI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 29/7/2017.
- Oba Atofarati (Oba Atofarati)
Apata Ayeraye (Apata Ayeraye)
Iwo ni O un se itoju gbogbo agbaye
Ko si eda kankan ti ko ye k’O juba Re
Eniyan ti O fi wa da l’a se wa juba Re
Kabiyesi o, Olorun iye.
Egbe: Kabiyesi, Olu aye, Olu orun
Oba nla, Alagbara, kabiyesi Re.
-
Oba Eledumare (Oba Eledumare)
Apa nla t’O s’aye ro (Apanla t’O s’aye ro)
Iwo ni ka bi O ko si ni gbogbo agbaye
Awa eru t’O so d’omo l’a wa juba Re
Igbala ti O fi fun wa l’a se wa juba Re
Kabiyesi o, Olorun ife. -
Oba Awimayehun (Oba Awimayehun)
Ibi isadi tooto (Ibi isadi tooto)
Iwo ni O un se’dari ni gbogbo agbaye
L’osan l’oru ni gbogbo wa ye k’a juba Re
Itoju Re igba gbogbo l’a se wa juba Re
Kabiyesi o, Olorun ayo. -
Oba Ologojulo (Oba Ologojulo)
Ibere ati Opin (Ibere at Opin)
Iwo ni yo se idajo fun gbogbo agbaye
T’agba t’ewe yo teriba l’ati juba Re
Idalare ti O fun wa l’a se wa juba Re
Kabiyesi o, Olorun ogo.