N KO NILO BABA ALAWO MO
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 3/7/2017.
- N ko nilo awon Baba alawo mo
N ko nilo awon woli eke mo rara o
Ohun gbogbo ti mo nilo l’aye mi o
Agbara Jesu mi kaa, o ka gbogbo won.
Egbe: O ti to fun mi o, o ti to.
O ti to fun mi o, o to mi
Ohun ti Jesu Kristi se’leri fun mi o
O ti to fun mi, e wa ba mi yo o.
-
Ogun idile ko yo mi ni enu mo
Ogun oso aje ko ma si l’oro mi mo o
Jesu Oluwa t’o un ti mi l’eyin o
O ti segun gbogbo won, ninu aye mi. -
Iberu iku ko si ni oro mi mo
Iye ainipekun ni Jesu mi ti fun mi
Ko si eni ti o le ge ojo mi kuru o
Ayeraye ologo, l’o nduro de mi.