MODUPE OLUWA, MO UN SUN MO UN JI, LAISI ‘YONU
Composed be Z. A. Ogunsanya Date: 28/8/2017.

 1. Modupe Oluwa, mo un sun mo un ji, laisi ‘yonu.
  Modupe Oluwa, mo un s’aseyori, l’enu ise mi
  Modupe Oluwa, fun abo t’O daju, ti O fi un bo mi.
  Mo dupe, mo dupe, Baba mo dupe o.

 2. Modupe Oluwa, pe O ti gbamila, O so mi d’omo
  Modupe Oluwa, pe O ti we mi mo, mo si di mimo
  Modupe Oluwa, fun Emi Mimo Re, t’O fun mi l’agbara.
  Mo dupe, mo dupe, Baba mo dupe o.

 3. Modupe Oluwa, fun Bibeli Mimo, t’O fi un bo mi
  Modupe Oluwa, f’awon onigbagbo, t’O fi yi mi ka
  Modupe Oluwa, fun isimi okan, ti O tun fi fun mi.
  Mo dupe, mo dupe, Baba mo dupe o.

 4. Modupe Oluwa, fun atileyin Re, ti mo un ri gba
  Modupe Oluwa, fun’toni Emi Re, t’O ns’akoso mi
  Modupe Oluwa, fun ile ologo, t’O lo pese fun mi.
  Mo dupe, mo dupe, Baba mo dupe o