MO TUN TI DE OLODUMARE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 9/2/2017.
Egbe: Mo tun ti de, Olodumare
Mo tun de l’oni mo wa gba’re t’emi
Baba ma je ki, emi lo l’ofo
Mo tun ti de o, mo wa gba’re Oluwa.
-
Nigbati Mose, de okun pupa
T’awon omo Israeli fe so ni okuta pa
Iwo l’O dahun, t’O p’okun niya
Wa da mi l’ohun, k’O si ilekun fun mi. -
Nigbati Hana, nsokun ni Shilo
Ti awon eniyan l’ero pe se l’o munti yo
Iwo l’O dahun, t’O si fun l’omo
Wa da mi l’ohun, k’O so ekun mi d’erin. -
‘Gbati Jabesi, omo ‘banuje
Gbadura pe ki O wa yi igba ohun pada
Iwo l’O dahun, t’O si bukun fun
Wa da mi l’ohun, y’igba mi pada s’ire. -
Gba Modikai, gbadura si O
‘Tori Hamani pinu l’ati gbe ko s’ori’gi
Iwo l’O dahun, t’O s’ohun titun
Wa da mi l’ohun, k’O s’ohun titun fun mi. -
Gba Jona ba’ra, re ninu eja
Ti o si dabi enipe ko si ireti mo
Ni’gba t’O dahun, l’eja po s’oke
Wa da mi l’ohun, ko mi yo ninu ewu. -
‘Gbati Josefu, fee ko Maria
Nitori ko mo bi oyun Jesu se de’nu re
Iwo l’O dahun, t’O yanju oro.
Wa da mi l’ohun, ba mi yanju oro mi. -
Ole ti a kan, mo agbelebu
Nigba ti o ku die ko wo orun apadi
Iwo l’O dahun, t’O mu lo s’orun
Wa da mi l’ohun, k’O mu mi de’le ogo.