MO TI L’ENI T’O LE BA MI SE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: Chorus:??, body: 6/2/2017
Egbe: Mo ti l’eni t’O le ba mi se
E ma yonu mo o
Ohun l’O ba’won ti’saaju se ti won
Jesu yi o ni un o maa f’eyin ti
Ko tun s’eni t’O le ba mi se
E ma yonu mo.
-
Ipa alawo ko ka, Onisegun ko le se
Eni t’O le yanju isoro aye eniyan
Ni Oba nla ti O da eniyan si aye
Ta wa ni o? (Jesu ni o)
Oun ni ko ni afiwe rara (rara o). -
Ko s’ebo ko s’ogungun, ko s’eniyan t’o le se
Eni t’O ba gbogbo awon ti’gbani se ti won
Ni Oba nla ti O tun le ba ni se l’oni
Ta wa ni o? (Jesu ni o)
Oun l’O ba awon ti’gbani se (yori o). -
Woli eke po l’aye, iro si po l’enu won
Eni t’Olorun pase pe ki a ma gbo ti Re
Ni Oba nla ti O le se ni aseyori
Ta wa ni o? (Jesu ni o)
Oun ni O le ba ni se yori (yori o). -
Egbe awo ko wulo, esin pelu ko le se
Eni t’O ni kokoro iku ati ti iye
Ni Oba nla ti O le pa esu l’enu mo
Ta wa ni o? (Jesu ni o)
Oun ni yo si ba mi se te mi (yori o).