MO GB’OJU MI LE O, OBA IYANU
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 13/5/2017.
During fasting and prayer at k’araole church.
Egbe: Mo gb’oju mi le O, Oba iyanu
Mo f’eyin mi ti O o, Atof’arati
Iwo ni mo di mu, wa tete ba mi se
Tete ba mi se o, k’o se yori o.
-
Iwo ni oke, oke t’o ga julo
Iwo ni ogbun, ogbun t’o jin julo
Iwo l’ate rere, rere kari aye
Wa fa ori mi, s’oke o. -
Iwo l’alewi, Alewi-Alese
Iwo l’orisun, orisun ti iye
Iwo ni Oluwa, t’o le s’ohun gbogbo
Wa bukun fun mi, l’oni o. -
Iwo ni ko si, aseti l’odo Re
Iwo nikan ni, ko ni igbakeji
Iwo nikan l’O le, so oku d’alaye
Wa so mi ji o, l’o ni o. -
Iwo l’O soro, t’O da ohun gbogbo
Iwo l’O pase, t’O si da eniyan
Iwo ni Alase, ni gbogbo agbaye
Wa p’ase iye, s’ori mi. -
Iwo ni ona, s’odo Olorun
Iwo l’O le pa, Esu l’enu mo
Iwo l’O ngbani, l’owo gbogbo ogun
So mi d’asegun, l’aye o. -
Iwo l’O le si, t’enikan ko le ti
Iwo l’O le ti, t’enikan ko le si
Iwo l’O ni koko-ro iku at’iye.
S’ilekun iye, fun mi o. -
Iwo ni oku, oku t’O ji dide
Iwo l’O goke, lo s’oke orun
Iwo yoo pada wa, lati se idajo
Wa da mi l’are, l’o ni o.