JESU YI O DARA SI MI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 30/7/2017.
- Jesu yi O dara si mi
O gbamila O si tun womisan
O fun mi ni Iye ainipekun
Jesu yi l’emi yo ma sin titi d’opin.
Egbe: O dara
Jesu yi dara yeye
O dara si mi.
-
Jesu yi ni O we mi mo
O fun ni agbara Emi Re
Ati opolopo ore-ofe Re
Jesu yi l’emi yo tele titi d’opin. -
Jesu yi O wulo fun mi
O nti mi l’eyin ni gbogbo ona
O si ba mi segun Esu ota mi
Jesu yi l’emi yo romo titi d’opin. -
Jesu yi yo mu mi de’le
N’igba ti mo ba fi aye sile
Yo mu mi lo s’ile Baba Re l’oke
Jesu yi l’emi yo ba gbe titi d’opin.