JESU IWO L’OBA L’ONI YI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 6/12/2017. As I got up from the bed in the morning.
- Jesu Iwo l’Oba l’oni yi
Oba l’ana, Oba l’ola, Oba titi aye
Oba ni O o, Baba ni ojo gbogbo.
Egbe: Oba, Oba nla ni O
Jesu Oluwa, Iwo nikan l’Oba
Ni gbogbo agbaye.
-
Jesu Iwo l’Oba l’ebi mi
Oba t’emi, ti aya mi, ti awon omo mi
Oba ni O o, Baba ninu Ile mi. -
Jesu Iwo l’Oba l’okan mi
Oba l’oro, Oba l’ero, n’iwa at’ise mi
Oba ni O o, Baba ninu aye mi. -
Jesu Iwo l’Oba l’aye yi
Oba l’aye, Oba l’orun, Oba n’ibi gbogbo
Oba ni O o, Baba l’aye at’orun.