JE K’O RI BE E SE UN FE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 3/1/2018.
Egbe: Je k’o ri be E se un fe (ninu aye mi)
Je k’o ri be E se un fe o (Baba mi l’orun)
Ero rere ti E ngba fun mi (ti E ngba fun mi o)
Baba je k’o se l’aseyori.
-
Ero Re ni wipe
K’emi je atunbi, at’olododo
K’emi j’eni mimo, at’alagbara
L’oju ona igbagbo, k’emi ma se w’eyin /2ice. -
Ero Re ni wipe
K’emi wa n’ilera, k’o dara fun mi
K’emi ni anito, k’ire je t’emi
L’ojo aye mi gbogbo, k’emi s’aseyori /2ice. -
Ero Re ni wipe
K’emi j’asoju Re, ni ibi gbogbo
K’emi jere okan, s’inu ijo Re
L’oju ona tooro yi, k’emi j’asiwaju /2ice. -
Ero Re ni wipe
K’emi le ni ipin, ‘nu igbasoke
K’emi ba o joko, l’ori ite Re
L’ayeraye alayo, k’emi ba o joba /2ice.