IWO NI OPE TOSI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 01/07/2017.
-
Iwo ni ope tosi
Iwo ni iyin ye fun o
Iwo ni ogo ye fun o
Eledumare ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Eledumare mo m’ope wa. -
Iwo l’Atogbojule
Iwo l’Atof’arati o
Iwo l’Atosimile o
Baba mi l’oke ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Baba mi l’oke mo m’ope wa. -
Iwo ni Olugbala
Iwo ni Oluwosan o
Iwo ni Olupese o
Olurapada ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Olurapada mo m’ope wa. -
Iwo l’abo t’o daju
Iwo ni orisun ayo
Iwo l’Onise iyanu
Jehofah Jireh ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Jehofa Jireh mo m’ope wa. -
Iwo ni ko l’afiwe
Iwo ni ko n’igbakeji
Iwo l’O le s’ohun gbogbo
Awimayehun ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Awimayehun mo m’ope wa. -
Iwo l’O da eniyan
Iwo l’O da ohun gbogbo
Iwo l’Oba t’O ga julo
Orisun iye ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Orisun iye mo m’ope wa. -
Iwo l’O ku t’O jinde
Ti O go ke lo si orun
Ti O un bo wa mu mi lo
Arugbo ojo ope ye o
Ope Re ree o (Jesu)
Arugbo ojo mo m’ope wa.