IWE MIMO L’O SO FUN WA WIPE, TI O KO BA GBA JESU
Composed by Z. A Ogunsanya Date: 17/3/2017. 1:07 am.
- Iwe Mimo l’o so fun wa wipe
Ti a ko ba gba Jesu, a ko le ri iye
Ti a ko ba gba Jesu, a ko le ni ayo t’o daju
Ti a ko ba gba Jesu o, a ko le ni ifokanbale tooto
Awon ti ko gba Jesu Kristi
Eni esin eni are ni gbogbo won je.
Egbe: Emi ko, (Emi ma ko o)
Mo ni kii s’emi, ni yo ko eyin re si Jesu o
Pata pata ni mo gba Jesu Oluwa gbo
K’emi le ri iye, iye ayeraye
Mo ti ri o (Mo ti ri /2ice.), iye ainipekun ni.
-
Iwe Mimo tun tenumo wipe
Awon ti ko ni Jesu, awon lo un d’ese
Awon ti ko ni Jesu, awon l’Esu un sakoso re
Awon ti ko ni Jesu o, awon ni o un se egbe okunkun.
Awon ti ko ni Jesu Kristi
Eru Esu ati ese ni gbogbo won je. -
Iwe Mimo tun fi ye wa wipe
Awon t’o ba ni Jesu, Esu ko ri won lo
Awon t’o ba ni Jesus, aye ko le ri won gbese
Awon t’o ba ni Jesu o, awon ni o ni iye ayeraye
Awon t’o ba ni Jesu Kristi
Omo Olorun alaye ni gbogbo won je. -
Iwe Mimo l’o kilo bayi wipe
Awon ti ko ni Jesu, won ko ni Olorun
Awon ti ko ni Jesu, won ko ni abo t’o daju
Awon ti ko ni Jesu o, won ko n’ibugbe n’ile ologo
Awon ti ko ni Jesu Kristi
Omo egbe at’iparun ni gbogbo won je.