IWE HEBERU NI, ORI EKERIN
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 22/02/2016
- Iwe Heberu ni, ori ekerin
Ese ikejila, l’o so bayi pe.Egbe: Oro Olorun o ye (o ye o
O si l’agbara (agbara)
O si mu ju ida (ida)
Oloju meji (oloju meji o). -
Bi mo ji l’owuro, ma ka Bibeli
Ki nto sun l’asale, ma ka Bibeli. -
Onigbagbo ranti, p’oro Olorun
Ni Jesu fi segun, Esu buburu. -
Mu Bibeli jade, mu si’gberi re
T’o ba ka Bibeli, yo sise fun o. -
Ka Bibeli ni’le, ka ni’bise re
Ka ni’rinajo re, ka nigba gbogbo. -
Ka Bibeli l’ale, ka ni owuro
Ka l’oganjo oru, ati ni osan. -
Ka s’eti omode, ka fun arugbo
Ka fun gbogbo ile, ati alaisan. -
Emi ni oro yi, iye ni pelu
Eni to mo’oro na, yo dominira. -
Oro yi l’agbara, l’ati wonisan
Oro yi ngbeniro, o ntu ni ninu. -
Oro yi ni’mole, si’pa ona wa
O tun je’da Emi, l’ati b’Esu ja. -
L’opin ohun gbogbo, oro Bibeli
Ni Olorun yoo lo, lati se’dajo. -
Eni t’o nsasaro, ninu Bibeli
Yo dabi igi ti, a gbin si’pado. -
Ko Bibeli s’ori, fi kun okan re
Maa fi se oro so, maa gba l’adura. -
Gboran si Bibeli, si maa wasu re
Fi ko gbogb’ebi re, at’aladugbo.