IRE T’ANA LARI T’A N WI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 10/4/2017. In my bathroom, Upon hearing from Bro. Olajide snr., that Nancy Olajide (Olajide Junior’s wife) has been granted American visa, that she had pursued for years.
- Ire t’ana lari t’a n wi (ti a n wi)
Eyi ti E tun se l’oni o (se l’oni o o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara.
Egbe: A wa dupe o (ope, ye O)
Atof’arati (Oba ogo)
A wa yin O o (Baba Mimo)
Awimayehun, E se, E se a dupe.
-
Ire t’igbala ni akoko (ni akoko)
Opo iyanu t’o tun te le (t’o tun te le o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara. -
Nit’imuse awon ileri (‘won ileri)
Ati idahun adura wa (adura wa o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara. -
Ise iwenumo okan wa (‘mo okan wa)
Ti ifikun ni Emi Mimo (Emi Mimo o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara. -
Niti abo Re ti ko l’egbe (ti ko l’egbe)
Alafia Re l’ona gbogbo (l’ona gbogbo o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara. -
Ibukun ati ipese Re (ipese Re)
Ati opo ore ofe Re (‘re ofe Re o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara. -
Ile ologo t’o lo pese (t’o lo pese)
Awon ere t’o nduro de wa (nduro de wa o)
Enu wa ko le royin re tan, rara rara.