HYMN – IBANUJE TI TAN, AYO L’O KU FUN MI

IBANUJE TI TAN, AYO L’O KU FUN MI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 5/6/2017. 3:15 am. After a successful prayer for the return of the last son of Brother Dada Jnr., whose news of being kidnaped reach me around 2:00 am. Meanwhile, his father had just been made the pastor of the new BPC church, in Odo Ayedun Ekiti which was inaugurated on 4/6/2017.

Egbe: Ibanuje ti tan
Ayo l’o ku fun mi
Olorun alagbara
L’o so ‘banuje mi d’ayo o.

 1. Esu gb’ogun dide
  Lati pa Hanna l’ekun
  Nipa airi omo bi fun ojo pipe
  Olorun Atofarati
  L’o wa so di iya olomo.

 2. Jabesi ko l’ayo
  Nitori ko nilari
  Omo ibanuje ni oruko ti won so
  Olorun Alagborodun
  L’o wa so di eni ibukun.

 3. Namani adete
  Olori ogun Siria
  Ti o wa ilera wa si odo Elisa
  Olorun Atogbojule
  L’o we ete re ni awemo.

 4. Mary Magdaleni
  T’o je elemi Esu
  Ti o gbe isoro re wa si odo Jesu
  Olorun ti ko le kuna
  L’o wa so di ominira o.

 5. Opo ti Naini
  T’o padanu omo re
  T’awon eniyan ti fe lo ba sin oku re
  Olorun Alewilese
  L’O so omo re di alaye.