FA WON TU BABA, ARUN AT’AISAN
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 12/5/2016 Translation to Yoruba at intercity Hotel Magdeburg Germany 27/5/2016.
1. Fa won tu Baba, arun at’aisan
At’awon arun t’emi, l’aye mi
Fun mi ni’wosan, ati ilera
F’alafia Re, kun aye mi.

Egbe:
Baba wa wo mi san, k’Esu ma daamu mi
Baba wa wo mi san, k’okan mi k’o bale
Baba wa wo mi san, k’emi le ri, b’o ti ye ki nri
Ba-ba ti O ba wo mi san, yo dara fun mi
‘Tori-na wa wo mi san, wa wo mi San
Jesu, mi wa wo mi san l’oni yi
Fun mi l’alafia.

 1. Iwe Eksodu, ori kedogun
  Ese ‘keridinlogbon, so wipe
  Arun Egypti, ki yo je te mi
  Iwo l’Oluwa, t’O nwo mi san.

 2. Nipa ina Re, l’a un wo wa san
  Aisan ko ni eto mo, l’aye mi
  Pa’se fun arun, ati aisan
  Ki won lo kuro, nin’aye mi.

 3. O fi ara da, opo isoro
  Bii ti gbogbo eniyan, nin’aye
  Sugbon iwo ko, saisan ni’gba kan
  Se mi bii tiRe, m’ara mi le.

 4. Epafroditu, at’opo miran
  Ninu Majemu Titun, se aisan
  ‘Gba won kepe O, O se ‘wosan won
  Ni ona kan na, wa wo mi san.

 5. O tun so fun wa, ninu oro Re
  Mo fe ki e wa ninu, ilera
  Ati anito, ko dara fun yin
  Wa m’oro Re se, k’O wo mi san.

 6. Aisan at’arun, ki’se ebun Re
  Won ko wulo l’aye mi, rarara
  Gba mi l’owo won, l’ojo aye mi
  K’emi le sin O, pelu ‘lera.

 7. Ninu Bibeli, gbogbo eniyan
  T’o be O fun iwosan, l’O wosan
  Aanu Re t’O fi, wo gbogbo won san
  Ran si emi na, k’O wo mi san.

 8. O ran oro Re, O tu won sile
  Ninu gbogbo arun won, at’aisan
  Ran oro kan na, sinu ara mi
  Ati emi mi, k’o wo mi san.