EMI MIMO WA BA LE MI O
Composed by Z. A. Ogunsnaya Date: 12/9/2016.
- Emi Mimo wa ba le mi o
Agborodun at’Olutunu
Emi t’O la’na l’aginju
F’awon omo Israeli.
Egbe: Tete maa bo o
Maa bo
K’O wa ba le mi o.
-
Emi Mimo wa ba le mi o
Emi ogbon at’Emi oye
Emi t’O gbe Solomoni
Wo t’o fi di oloro. -
Emi Mimo wa ba le mi o
Emi agbara l’ati oke
Emi t’O gbe Elijah wo
T’o fi ji oku dide. -
Emi Mimo wa ba le mi o
Emi akoni l’oju ija
Emi t’O gbe Dafidi wo
T’o segun Golayati. -
Emi Mimo wa ba le mi o
Emi iye at’Oluwosan
Emi t’O gbe Peteru wo
T’o fi m’aro larada. -
Emi Mimo wa ba le mi o
If’ororo yan l’ati oke
Iwo ti O gbe Paulu wo
T’o fi se ‘se iyanu. -
Emi Mimo wa ba le mi o
Oludari at’Olufihan
Emi t’O ba le Johanu
T’o fi ri iran orun.