E LO O, E LO SI GBOGBO AYE
Composed by Z. A .Ogunsanya Date: 15/7/2017. In my bathroom.
-
E lo o, e lo si gbogbo aye
E so fun won wipe Jesu Olugbala ku
O ku fun won o, O si tun ji dide
Ki won ma ba segbe, egbe ayeraye
Enit’o ba gba Jesu gbo
Yo ni iye ainipekun
Eniti ko ba gba Jesu gbo o
Yo lo s’orun egbe, egbe ayeraye
B’o se elesin l’o je (yo lo s’orun egbe o)
B’o se omoluabi ni (yo lo s’orun egbe o)
Eniti ko ba gba Jesu gbo o
Yo lo s’orun egbe, egbe ayeraye
E tete lo so fun won o (fun t’omode t’agba won)
Ki won ko le gba Jesu l’Oba o
Ki won ma ba segbe, egbe ayeraye. -
E so o, e so f’elese wipe
Iku ni ere ese fun gbogbo araye
Iku ti ara, ati iku keji
Ni orun apadi, n’ibi ise oro
Eniti ko gba Jesu gbo
Eru Esu ni ninu aye
Eniti ko ba ronupiwada
Ko ni le ri iye, iye ayeraye
B’o un rele Ijosin (ko ni le ri iye o)
B’o un san idamewa (ko ni le ri iye o)
Eniti ko ba ronupiwada
Ko ni le ri iye, iye ayeraye
E tete lo fi ye won o (e ke’gbe si won l’eti)
Ki won ko le ronupiwada o. -
E tun so, fun awon onigbagbo
Yo dara fun won ni Olorun alaye wi
Ninu aye yi, ati l’ayeraye
E lo f’okanbale, Jesu ti to fun yin
Toripe e gba Jesu gbo
Ni e se bo ni owo Esu
Toripe e ti gba Jesu gbo o
L’e se d’om’Olorun, ati ominira
Bi Esu fe b’Esu ko (E ti d’ominira)
Ohun yowu k’o sele (E ti d’ominira)
Toripe e ti gba Jesu gbo o
L’e se d’om’Olorun, ati ominira
E tete lo fi ko won o (e je ko ye won yeke)
Ki won ko le taku ti Jesu o.