E HO IHO AYO
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 13/6/2017.
-
E ho iho ayo
E yin Baba l’ogo
E ko’rin iyin si
Olorun ayo. -
E gb’owo yin s’oke
E gb’ohun yin s’oke
E f’oribale fun
Olorun ogo ni. -
E kede f’araye
Igbala ofe Re
Ise iyanu Re
Olorun ife ni. -
E t’eti s’oro Re
E tele ase Re
K’e si se ife Re
Olorun mimo ni. -
E gbe eke yin le
E gb’oju s’oke si
E simi l’oro Re
Olorun iye ni.