BABA WA TI NBE L’ORUN, OLORUN ELEDA WA
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 3/9/2017. In the bathroom on a Sunday night.

 1. Baba wa ti nbe l’orun, Olorun wa, Eleda wa
  Alagbara giga julo, a gbe O ga l’ojo oni yi.

Egbe: Olorun wa, Iwo l’O ga julo
Ko tun s’oba kan t’o da bi Re
Odo Re nikan n’ireti wa wa
Titi aye l’a o gbekele O.

 1. Iwo ni a ni l’ana, Iwo nikan l’a ni l’oni
  Iwo n’ireti wa l’ola, a gbe oju wa s’oke si o.

 2. Ipa Re ko l’afiwe, ase Re kari agbaye
  Iwo l’O le s’ohun gbogbo, a f’igbekele wa s’odo Re.

 3. Ileri Re l’agbara, Iwo l’abo t’O ga julo
  Atileyin Re ko l’egbe, a nw’ona fun iranwo Re si.

 4. N’igbati a wa l’aye, Iwo ni Olutoju wa
  Ati l’ayeraye pelu, odo Re ni itura wa wa.