BABA T’O SE’GUN FARAO
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 5/8/2017. On my bed, 1:30 am.
- Baba t’O se’gun farao (iyanu ni O)
Baba t’O pin okun n’iya (iyanu ni O)
Baba t’O la ona l’aginju
Iyanu l’agbara Re Baba
Iyanu ni O.
Egbe: Iyanu, n’ise Re Oluwa
Iyanu o, n’ise Re o Baba.
-
Baba t’O se’pese mana (iyanu ni O)
Baba t’O w’odi Jeriko (iyanu ni O)
Baba t’O so mara di didun
Iyanu l’ogbon Re o Baba
Iyanu ni O. -
Baba t’O ngba elese la (iyanu ni O)
Baba t’O nsoni di mimo (iyanu ni O)
Baba t’O nfi agbara kun ni
Iyanu n’igbala Re Baba
Iyanu ni O. -
Baba t’O nmu amukun rin (iyanu ni O)
Baba t’O nmu odi fo’hun (iyanu ni O)
Baba t’O nla eti aditi
Iyanu n’ife Re o Baba
Iyanu ni O. -
Baba t’O nwe adete mo (iyanu ni O)
Baba t’O nji oku dide (iyanu ni O)
Baba t’O l’a oju afoju
Iyanu n’ise Re o Baba
Iyanu ni O. -
Baba t’O ku t’O tun jinde (iyanu ni O)
Baba t’O goke lo s’orun (iyanu ni O)
Baba t’O nbebe fun wa l’orun
Iyanu l’anu Re o Baba
Iyanu ni O.