BABA GBA OPE TI MO MU WA
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 20/1/2016.
Egbe: Baba, gba ope ti mo mu wa
Gba iyin ti mo mu wa o
Ojojumo ni un o ma gbe o ga
Fun ore Re t’O se fun mi.
-
Ti mo ba ji l’owuro, maa f’oribale fun O
Ti mo ba de’bi ise, maa se kiki ife Re
Ti mo ba de ile l’ale, iyin ogo ni mo ma fi fun O -
Iwe Mimo Bibeli, ni yo se amona mi
Adura igba gbogbo, ni aye mi yo kun fun
Awon eni mimo tooto, nikan ni yo je alabarin mi. -
Ninu ile ijosin, ma korin ogo si O
T’oro Re ba un jade, ma f’etibale gbo O
Bi mo d’arin awujo, ihinrere Re ni mo ma kede. -
L’ona gbogbo ti mo mo, l’emi yo wulo fun O
Owo, owo at’ebun, mi l’emi yo fi sin O
Gbogbo eni t’o yi mi ka, l’emi yo ma fi ife Re han fun. -
Ni’po yowu ti mo wa, emi yoo gbekele O
Nigba t’Esu ba nhale, igbagbo mi ko ni ye
Ni gbogbo ojo aye mi, Jesu Oluwa ni mo ma tele. -
Nigba t’aye ba pari, mo ni’bugbe l’odo Re
Ti Jesu mi lo pese, fun gbogbo onigbagbo
Eni ba f’ori tii d’opin, ni ki yoo padanu ile ogo.