BABA ELEDUMARE, MO NILO RE O, NINU AYE MI
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 26/5/2017. During night vigil at karaole.
- Baba Eledumare
Mo nilo Re o, ninu aye mi
Mo nilo Re o, ninu okan mi
Baba n’owo agbara Re o
K’O wa se’yanu Re fun mi
K’O si tete se yori.
Egbe: L’oruko Jesu Oluwa
Nitoripe, laisi ‘ranwo Re Oluwa
Esu a s’eniyan jatijati.
-
Baba Awimayehun
Mo nilo Re o, ninu ile mi
Mo nilo Re o, ninu ise mi
Baba s’ilekun Re fun mi o
Ro’jo ‘bukun Re s’ori mi
Ati s’ori ile mi. -
Baba Atof’arati
Mo nilo Re o, fun aseyori
Mo nilo Re o, fun ‘fokanbale
Baba ran ‘bukun Re si mi o
K’o si fun mi n’isimi Re
Ati itelorun Re. -
Baba Eleruniyin
Mo nilo Re o, ni ojo gbogbo
Mo nilo Re o, ni ibi gbogbo
Baba wa d’abo Re bo mi o
Ba mi pa Esu l’enu mo
K’o si fun mi n’isegun. -
Baba mi t’O npada bo
Mo nilo Re o, ninu aye yi
Mo nilo Re o, ni ayeraye
Baba di mi mu de opin o
K’o si de mi ni ade Re
N’ile Re l’oke orun.