ALAYO NI MI, NINU JESU O
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 13/9/2017. The song came as I
was thinking about a sorrow creating problem, that was reported to me the previous night.
Egbe: Alayo ni mi, ninu Jesu o
Alayo ni mi, l’ojo oni o
Alayo ni mi, l’ojo aye mi gbogbo.
-
Jesu, l’O fun mi l’ayo
Ayo t’isoro, ko le mu kuro ni
Ayo yi ko nii, se pelu ipo mi l’aye. -
Ayo, ti mo ni l’okan
Ayo ti aye, ko le r’idi re ni
Eleruniyin, l’O fun mi l’ayo ti mo ni. -
Ayo, yi dara pupo
Ayo ti aye, ko le f’owo kan ni
Ayo ti Baba, Omo, ati Emi Mimo. -
Ayo, ti mo nsoro re
Ayo ti ko si, n’ibomiran ma ni
O yato si idunnu ti awon elese. -
Ayo, t’owo le fun ni
Ayo ti ko ni, ifokanbale ni
Jesu Oluwa, l’O l’ayo otito l’owo. -
Ayo, t’aye le fun ni
Ayo t’abamo, yo je opin re ni
Jesu mi nikan, l’Orisun ayo t’o daju. -
Ayo, ti Jesu Kristi
Ayo ti ko ni, igbakeji ma ni
Ayo t’o t’aye, lo s’ayeraye alayo.