MO TUN TI DE OLODUMARE
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 9/2/2017.

Egbe: Mo tun ti de, Olodumare
Mo tun de l’oni mo wa gba’re t’emi
Baba ma je ki, emi lo l’ofo
Mo tun ti de o, mo wa gba’re Oluwa.

 1. Nigbati Mose, de okun pupa
  T’awon omo Israeli fe so ni okuta pa
  Iwo l’O dahun, t’O p’okun niya
  Wa da mi l’ohun, k’O si ilekun fun mi.

 2. Nigbati Hana, nsokun ni Shilo
  Ti awon eniyan l’ero pe se l’o munti yo
  Iwo l’O dahun, t’O si fun l’omo
  Wa da mi l’ohun, k’O so ekun mi d’erin.

 3. ‘Gbati Jabesi, omo ‘banuje
  Gbadura pe ki O wa yi igba ohun pada
  Iwo l’O dahun, t’O si bukun fun
  Wa da mi l’ohun, y’igba mi pada s’ire.

 4. Gba Modikai, gbadura si O
  ‘Tori Hamani pinu l’ati gbe ko s’ori’gi
  Iwo l’O dahun, t’O s’ohun titun
  Wa da mi l’ohun, k’O s’ohun titun fun mi.

 5. Gba Jona ba’ra, re ninu eja
  Ti o si dabi enipe ko si ireti mo
  Ni’gba t’O dahun, l’eja po s’oke
  Wa da mi l’ohun, ko mi yo ninu ewu.

 6. ‘Gbati Josefu, fee ko Maria
  Nitori ko mo bi oyun Jesu se de’nu re
  Iwo l’O dahun, t’O yanju oro.
  Wa da mi l’ohun, ba mi yanju oro mi.

 7. Ole ti a kan, mo agbelebu
  Nigba ti o ku die ko wo orun apadi
  Iwo l’O dahun, t’O mu lo s’orun
  Wa da mi l’ohun, k’O mu mi de’le ogo.