E YARA KO GBOGBO RE WA O
Composed by Z. A. Ogunsanya  Date: 9/12/2016.

Egbe: E yara gbe gbogbo re wa o (Omode e gbo, agbagba e gbo), (Gbogbo eniyan e teti gbo)
E yara gbe gbogbo re wa o (onile, alejo)
Ohunkohun t’o nyo yin l’enu (l’ona kan kan)
E gbe won wa s’odo Jesu o
Ki e tete gbe won wa.

 1. Awon isoro ti won un gbe wa
  Si odo Jesu l’ati’bi gbogbo
  Ko s’eyi t’agbara Jesu ko ka
  Logan ni Jesu nbojuto won
  Bi won ti un fe.

 2. Obinrin onisun eje t’o wa
  Pelu isoro odun mejila
  Ti gbogbo aye ti se tire ti
  Logan ni Jesu yanju re fun
  T’o si di Mimo.

 3. Okunrin ti a bi ni afoju
  Ti o wa ni’bi t’o ti un sh’agbe
  Ko mo p’Olorun fe gba t’oun ro
  Logan ni Jesu la’ju re fun
  T’o si tun riran.

 4. Okunrin alarun egba un ko
  Ti eni merin gbe to Jesu wa
  Ti awon farisi fe dena re
  Logan ni Jesu mu l’arada
  T’o si lo si’le.

 5. Lasaru t’o ti ku f’ojo merin
  Ti won si ti gbe sinu iboji
  Bi Jesu ti pase pe k’o jade
  Logan ni’ye Jesu wo’nu re
  To si jade wa.

 6. Baba ti omo re nku warapa
  T’awon omo eyin ko le wo san
  B’o ti ke’gbe si Jesu fun ‘ranwo
  Logan ni Jesu w’omo re san
  T’o d’ominira.

 7. Ogbeni asinwin ti Gadara
  Ti o f’iboji se ile gbigbe
  Ti legioni un gbe inu re
  Logan ni Jesu m’ori re pe
  T’o si lo s’ile.

 8. Ni igba ti waini tan ni Kana
  Ti won bere iranlowo Jesu
  Omi ti won ni sinu ikoko
  Logan ni Jesu so di waini
  Ti gbogbo won mu.

 9. L’ojo t’iji dide ninu okun
  Ti won ke’gbe si Jesu k’O gba won
  Jesu so fun iji k’o dake je
  Logan n’idakeroro si de
  Ti won si gunle.

 10. T’iwo pelu ba gbe ‘soro re wa
  Si odo Jesu ni ojo oni
  Jesu ko ni je ki oju ti o
  Logan ni Yo ba o se ti re
  Ti o ba le wa.