ARAYE O, E WA GBA JESU L’OBA
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 13/4/2017.
- Araye o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Aye ti e gbojule ofo l’o je o
Araye o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, ni ireti ogo.
Egbe: O daju pe asan l’aye je, asan l’aye je
O daju pe ofo l’aye je, ofo l’aye je
Imulemofo o, ma l’aye je o /2ice.
-
Olowo o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Owo ti e gbojule ko le gbanila
Olowo o, e wa gba Jesu l’Oba.
Jesu o, nikan l’Olugbala. -
Arugbo o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Omo ti e gbojule le gbagbe yin o
Arugbo o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, ni awimayehun. -
Omode o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Obi ti e gbojule ma le ku l’ola
Omode o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, l’Oba ayeraye. -
Onile o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Ile ti e gbojule ma le jona o
Onile o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, l’Atofarati o. -
Oloogun o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Ewe ti e gbojule ma le sun’ko o
Oloogun o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, l’O ni gbogb’agbara. -
Ariran o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Iran ti e gbojule le tan yin je o
Ariran o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, l’Otito at’iye. -
Elesin o, e wa gba Jesu l’Oba /2ice.
Esin ti e gbojule ko le gba yin la
Elesin o, e wa gba Jesu l’Oba
Jesu o, l’O le gba yin la o.