HYMN – OLUWA, OLORUN MI, OUNGBE T’O NGBE MI

OLUWA, OLORUN MI, OUNGBE T’O NGBE MI
Composed by Z. A. Ogunsanya, 7/6/2019. In my room, while working on the prayer requests for the third day of three day fasting and prayer.

1. Oluwa, Olorun mi, oungbe t’o ngbe mi
Ki i se ti omi, ti halleluya ni
Mo fe k’alleluya, pelu awon ara
Ti won nwoju Oluwa
Niti igbeyawo, niti omo bibi
At’isoro idile, pelu oro t’ise.

Egbe: Tete da won lohun
           K’emi le ba won jo
           K’emi le ba won yo
          K’a le k’alleluya repete (repete o)
          K’a le k’alleluya repete.

2. Oluwa, Olorun mi, ohun ti mo un so
O nkamilara ni, ni ti halleleya
Eyi ti mo fe ke, pelu awon ara
Ti won nwoju Oluwa
Niti ile iwe, niti idanwo ni
Tabi ti igbese, eyi ti won fe san.
3. Oluwa, Olorun mi, oro mi ko i tan
O si jemilogun, o se iyebiye
K’emi k’alleluya, pelu awon ara
Ti won nwoju Oluwa
Niti aisan won, ti o nni won l’ara
At’awon t’o nronu, nitori isoro
Ti o nyo won l’enu, ti o npa won l’ekun.

4. Oluwa, Olorun mi, emi pelu un ko
Mo ti un gbadura, l’ori ohun pupo
Mo fe k’alleluya, mo fe j’ijo ope
Mo ti nwoju Oluwa
L’ori idile mi, aya (oko) awon omo
Ati gbogbo ebi, k’aye wa k’o toro
K’a le rije, rimu, k’awa ma se segbe.

Egbe: Tete da wa lohun
            K’awa le mu’jo jo
           K’awa le bu s’ayo
           K’a le k’alleluya repete (repete o)
           K’a le k’alleluya repete.