OPELOPE RE, BABA MIMO


OPELOPE RE, BABA MIMO
Composed by Z. A. Ogunsanya Date: 01/03/2017.

Egbe: Opelope Re, Baba Mimo /2ice.
Opelope Re Baba)
Ni ko je k’oju ti mi) /2ice.

 1. Nigba t’e ru un ba mi
  T’Esu un fe’ju mo mi
  Opelope Re Baba
  Ni ko je k’Esu bori.

 2. Nigba t’igbi aye de
  T’ese mi ko mule mo
  Opelope Re Baba
  Ni ko je k’e mi subu.

 3. Nigba ti’rewesi de
  Ti mo fe bojuw’eyin
  Opelope Re Baba
  Ni ko je k’emi w’eyin.

 4. Nigba ti ore ko si
  Ti nko r’eni f’oro lo
  Opelope Re Baba
  L’O s’alagborodun mi.

 5. Nigba ti aisan de
  Ti mo si fere ku tan
  Opelope Re Baba
  L’O fun mi ni iwosan.

 6. Nigba t’oro mi daru
  Ti nko m’ohun t’o kan mo
  Opelope Re Baba
  L’O si mi l’oju Emi.

 7. Nigba ti’nu mi baje
  Ti gbogbo re wa su mi
  Opelope Re Baba
  L’O pamilerin ayo.

 8. Nigba t’Esu ndan mi wo
  T’ese si tun un wu mi
  Opelope Re Baba
  L’O fi ‘gbagbo mi mule.

 9. Nigba mo siyemeji
  Ti mo fe pada s’aye
  Opelope Re Baba
  Ni ko je k’emi segbe.

 10. Nigba ti mo f’ese ko
  T’Esu wa ti mi subu
  Opelope Re Baba
  Ni mo se tun le dide.

 11. Nigba mo rin ‘rin ajo
  T’oko mi fere danu
  Opelope Re Baba
  L’O pa iji l’enu mo.

 12. Nigba ti mo gbadura
  L’ori oro aye mi
  Opelope Re Baba
  L’O fun mi ni eri je.